2 Samuel 3:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Joabu kúrò lọ́dọ̀ Dafidi, ó ranṣẹ lọ pe Abineri, wọ́n sì dá a pada láti ibi kànga Sira, ṣugbọn Dafidi kò mọ nǹkankan nípa rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Joabu si jade kuro lọdọ Dafidi, o si ran awọn iranṣẹ lepa Abneri, nwọn si pè e pada lati ibi kanga Sira: Dafidi kò si mọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Jóábù sì jáde kúrò lọ́dọ̀ Dáfídì, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ láti lépa Ábínérì, wọ́n sì pè é padà láti ibi kànga Sírà: Dáfídì kò sì mọ̀.