2 Samuel 3:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Abineri pada dé Heburoni, Joabu mú un lọ sí kọ̀rọ̀ kan, níbi ẹnubodè, bí ẹni pé ó fẹ́ bá a sọ ọ̀rọ̀ àṣírí, Joabu bá fi nǹkan gún un ní ikùn. Bẹ́ẹ̀ ni Abineri ṣe kú, nítorí pé ó pa Asaheli arakunrin Joabu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Abneri si pada si Hebroni, Joabu si ba a tẹ̀ larin oju ọ̀na lati ba a sọ̀rọ li alafia, o si gún u nibẹ labẹ inu, o si kú, nitori ẹjẹ Asaheli arakunrin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ábínérì sì padà sí Hébírónì, Jóabù sì bá a tẹ̀ láàrin ojú ọ̀nà láti bá a sọ̀rọ̀ ní àlàáfíà, ó sì gún un níbẹ̀ lábẹ́ inú, ó sì kú, nítorí ẹ̀jẹ̀ Ásáhẹ́lì arákùnrin rẹ̀.