2 Samuel 3:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi pàṣẹ pé kí Joabu ati àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fa aṣọ wọn ya, kí wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ Abineri. Nígbà tí ó tó àkókò láti sìnkú Abineri, Dafidi ọba pàápàá tẹ̀lé òkú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si wi fun Joabu ati fun gbogbo enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ pe, Ẹ fa aṣọ nyin ya, ki ẹnyin ki o si mu aṣọ-ọ̀fọ, ki ẹnyin ki o si sọkun niwaju Abneri. Dafidi ọba tikararẹ̀ si tẹle posi rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì wí fún Jóábù àti fún gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ fa aṣọ yín ya, kí ẹ̀yin sì mú aṣọ-ọ̀fọ̀, kí ẹ̀yín sì sunkún níwájú Ábínérì.” Dáfídì ọba tìkararẹ̀ sì tẹ̀lẹ́ pósí rẹ̀.