2 Samuel 3:34 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn kò dì ọ́ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dì ọ́ lẹ́sẹ̀; o ṣubú bí ìgbà tí eniyan ṣubú níwájú ìkà.” Gbogbo eniyan sì tún bú sẹ́kún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A kò sa dè ọ li ọwọ́, bẹ̃ li a kò si kàn ẹsẹ rẹ li abà: gẹgẹ bi enia iti ṣubu niwaju awọn ikà enia, bẹ̃ni iwọ ṣubu. Gbogbo awọn enia na si tun sọkun lori rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A kò sáà dè ọ́ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò kan ẹsẹ̀ rẹ ní àbà. Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń ṣubú níwájú àwọn ìkà ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ ṣubú.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì tún sọkún lórí rẹ̀.