2 Samuel 3:35 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo eniyan rọ Dafidi, pé kí ó jẹun ní ọ̀sán ọjọ́ náà ṣugbọn ó búra pé kí Ọlọrun pa òun bí òun bá fi ẹnu kan nǹkankan títí tí ilẹ̀ yóo fi ṣú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati gbogbo enia si wá lati gbà Dafidi ni iyanju ki o jẹun nigbati ọjọ si mbẹ, Dafidi si bura wipe, Bẹ̃ni ki Ọlọrun ki o ṣe si mi, ati ju bẹ̃ lọ, bi emi ba tọ onjẹ wò, tabi nkan miran, titi õrun yio fi wọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì wá láti gba Dáfídì ní ìyànjú kí ó jẹun, nígbà tí ọjọ́ sì ń bẹ, Dáfídì sì búra wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí èmi yóò bá tọ́ ounjẹ wò, tàbí nǹkan mìíràn títí òòrùn yóò fi wọ̀!”