2 Samuel 3:39 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ní, “Agbára mi dínkù lónìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òróró ni a fi yàn mí ní ọba. Ìwà ipá àwọn ọmọ Seruaya yìí ti le jù fún mi. OLUWA nìkan ni ó lè san ẹ̀san fún eniyan burúkú gẹ́gẹ́ bí ìwà ìkà rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi si ṣe alailagbara loni, bi o tilẹ jẹ pe a fi emi jọba; awọn ọkunrin wọnyi ọmọ Seruia si le jù mi lọ: Oluwa ni yio san a fun ẹni ti o ṣe ibi gẹgẹ bi ìwa buburu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi sì ṣe aláìlágbára lónìí, bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé a fi èmi jọba; àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ọmọ Saerúíà sì le jù mí lọ: OLÚWA ni yóò san án fún ẹni tí ó ṣe ibi gẹ́gẹ́ bí ìwà búburú rẹ̀!”