2 Samuel 3:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọ̀rọ̀ náà bí Abineri ninu gidigidi, ó bi Iṣiboṣẹti pé, “Ṣé o rò pé mo jẹ́ hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí Saulu laelae? Àbí ẹ̀yìn àwọn ará Juda ni ẹ rò pé mo wà ni? Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni mo ti jẹ́ olóòótọ́ sí Saulu baba rẹ, àwọn arakunrin rẹ̀ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, èmi ni n kò sì ti jẹ́ kí apá Dafidi ká ọ. Ṣugbọn lónìí ńkọ́, ò ń fi ẹ̀sùn kàn mí nípa obinrin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Abneri si binu gidigidi nitori ọ̀rọ wọnyi ti Iṣboṣeti sọ fun u, o si wipe, Emi iṣe ori aja bi? emi ti mo mba Juda jà, ti mo si ṣanu loni fun idile Saulu baba rẹ, ati fun ará rẹ̀, ati awọn ọrẹ rẹ̀, ti emi kò si fi iwọ le Dafidi lọwọ, iwọ si ka ẹ̀ṣẹ si mi lọrùn nitori obinrin yi loni?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ábínérì sì bínú gidigidi nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti Iṣibósẹ́tì sọ fún un, ó sì wí pé, “Èmi jẹ́ bí orí ajá ti Júdà bí? Di òní yìí ni mọ ṣàáánú fún ìdílé Ṣọ́ọ̀lù bàbá rẹ, àti fún àwọn arákùnrin rẹ̀, àti fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, tí èmi kò sì fi ọ́ lé Dáfídì lọ́wọ́, ìwọ sì kà ẹ̀ṣẹ̀ sí mí lọ́rùn nítorí obìnrin yìí lóní?