2 Samuel 4:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ẹni tí ó wá ròyìn ikú Saulu fún mi ní Sikilagi rò pé ìròyìn ayọ̀ ni òun mú wá fún mi, ṣugbọn mo ní kí wọn mú un kí wọ́n pa á. Ó jẹ èrè ìròyìn ayọ̀ rẹ̀, tí ó mú wá fún mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ẹnikan rò fun mi pe, Wõ, Saulu ti kú, li oju ara rẹ̀ on si jasi ẹni ti o mu ihin rere wá, emi si mu u, mo si pa a ni Siklagi, ẹniti o ṣebi on o ri nkan gbà nitori ihin rere rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ẹnìkan rò fún mi pé, ‘Wò ó, Ṣọ́ọ̀lù ti kú,’ lójú ara rẹ̀ òun sì jásí ẹni tí ó mú ìhìnrere wá, èmi sì mú un, mo sì pa á ní Síkílágì, ẹni tí ó ṣebí òun ó rí nǹkan gbà nítorí ìhìn rere rẹ̀.