2 Samuel 4:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Báwo ni yóo ti burú tó fún àwọn ẹni ibi, tí wọ́n pa aláìṣẹ̀ sórí ibùsùn ninu ilé rẹ̀? Ṣé n kò ní gbẹ̀san pípa tí ẹ pa á lára yín, kí n sì pa yín rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Melomelo ni, nigbati awọn ikà enia pa olododo enia kan ni ile rẹ̀ lori ibusun rẹ̀? njẹ emi ha si le ṣe alaibere ẹjẹ rẹ̀ lọwọ nyin bi? ki emi si mu nyin kuro laiye?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mélòó mélòó ni, nígbà tí àwọn ìká ènìyàn pa olódodo ènìyàn kan ni ilé rẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀—ǹjẹ́ èmi ha sì lè ṣe aláìbéèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yín bí? Kí èmi sì mú yín kúrò láàyè.”