2 Samuel 4:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n sì pa Rekabu ati Baana. Wọ́n gé ọwọ́ wọn, ati ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sì so wọ́n kọ́ lẹ́bàá adágún tí ó wà ní Heburoni. Wọ́n gbé orí Iṣiboṣẹti, wọ́n sì sin ín sí ibojì Abineri ní Heburoni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si fi aṣẹ fun awọn ọdọmọkunrin rẹ̀, nwọn si pa wọn, nwọn si ke ọwọ́ ati ẹṣẹ wọn, a si fi wọn ha lori igi ni Hebroni. Ṣugbọn nwọn mu ori Iṣboṣeti, nwọn si sin i ni iboji Abneri ni Hebroni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì fi àṣẹ fún àwọn ọdọ́mọkùnrin rẹ̀, wọ́n sì pa wọ́n, wọ́n sì gé ọwọ́ àti ẹṣẹ̀ wọn, a sì fi wọ́n há lórí igi ní Hébírónì. Ṣùgbọ́n wọ́n mú orí Íṣíbóṣétì, wọ́n sì sin ín ní ibojì Ábínérì ní Hébírónì.