2 Samuel 4:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Iṣiboṣẹti ní àwọn ìjòyè meji kan, tí wọ́n jẹ́ aṣaaju fún àwọn tí wọ́n máa ń dánà káàkiri. Orúkọ ekinni ni Baana, ti ekeji sì ni Rekabu, ọmọ Rimoni, ará Beeroti, ti ẹ̀yà Bẹnjamini. (Ẹ̀yà Bẹnjamini ni wọ́n ka Beeroti kún.)
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ Saulu si ni ọkunrin meji ti iṣe olori ẹgbẹ ogun: a npe orukọ ọkan ni Baana, ati orukọ keji ni Rekabu, awọn ọmọ Rimmoni ara Beeroti ti awọn ọmọ Benjamini: (nitoripe a si ka Beeroti pẹlu Benjamini:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì ní ọkùnrin méjì tí í ṣe olórí ẹgbẹ́ ogun: a ń pe orúkọ ọ̀kan ní Báánà, àti orúkọ ìkẹjì ní Rákábù, àwọn ọmọ Rímímónì ará Béérótì ti àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì (nítorí pé a sì ka Béérótì pẹ̀lú Bẹ́ńjámínì).