2 Samuel 4:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kan, Rekabu ati Baana, àwọn ọmọ Rimoni ará Beeroti, gbéra, wọ́n lọ sí ilé Iṣiboṣẹti, wọ́n débẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀sán, ní àkókò tí Iṣiboṣẹti ń sun oorun ọ̀sán lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Rimmoni, ara Beeroti, Rekabu ati Baana si lọ, nwọn si wá si ile Iṣboṣeti li ọsangangan, on si dubulẹ lori ibusun kan li ọjọkanri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Rímímónì, ará Béérótì, Rákábù àti Báánà sì lọ wọ́n sì wá sí ilé Iṣíbóṣétì ní ọsán gangan, òun sì sinmi lórí ibùsùn kan ní ọjọ́ kan-rí.