2 Samuel 4:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Oorun ti gbé obinrin tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà, tí ń fẹ́ ọkà lọ́wọ́ lọ, ó sùn lọ fọnfọn. Rekabu ati Baana bá rọra yọ́ wọlé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si wõ, nwọn si wá si arin ile na, nwọn si ṣe bi ẹnipe nwọn nfẹ mu alikama; nwọn si gun u labẹ inu: Rekabu ati Baana arakunrin rẹ̀ si sa lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sì wò ó, bí Olùsọ́ ẹnú ọ̀nà ilé náà ti ń gbọn àwọn pàǹtí, ó tòògbé ó sì sùn lọ, wọ́n sì wá sí àárin ilé náà, wọ́n sì ṣe bí ẹni pé wọ́n ń fẹ́ mú àlìkámà; (wọ́n sì gún un lábẹ́ inú: Rékábù àti Báánà arákùnrin rẹ̀ sì sá lọ).