2 Samuel 4:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n wọlé, wọ́n bá a níbi tí ó sùn sí lórí ibùsùn ninu yàrá rẹ̀, wọ́n lù ú pa, wọ́n sì gé orí rẹ̀. Wọ́n gbé orí rẹ̀, wọ́n gba ọ̀nà àfonífojì odò Jọdani lọ, wọ́n sì fi gbogbo òru ọjọ́ náà rìn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn wọ ile na lọ, on si dubulẹ lori ibusun rẹ̀ ninu iyẹwu rẹ̀, nwọn si lu u pa, nwọn si bẹ ẹ li ori, nwọn gbe ori rẹ̀, nwọn si fi gbogbo oru rìn ni pẹtẹlẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n wọ ilé náà lọ, òun sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀ nínú iyàrá rẹ̀, wọ́n sì pa á, wọ́n sì bẹ́ ẹ lórí, wọ́n gbé orí sá lọ, wọ́n sì fi gbogbo òru rìn ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà.