2 Samuel 4:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n dé Heburoni, wọ́n gbé orí rẹ̀ tọ Dafidi ọba lọ, wọ́n sì wí fún un pé, “Orí Iṣiboṣẹti, ọmọ Saulu, ọ̀tá rẹ, tí ó ń wá ọ̀nà láti pa ọ́ nìyí; oluwa mi, ọba, OLUWA ti mú kí ó ṣeéṣe láti gbẹ̀san, lára Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si gbe ori Iṣboṣeti tọ̀ Dafidi wá ni Hebroni, nwọn si wi fun ọba pe, Wõ, ori Iṣboṣeti ọmọ Saulu ọta rẹ, ti o ti nwá ẹmi rẹ kiri; Oluwa ti gbẹ̀san fun ọba oluwa mi loni lara Saulu ati lara iru-ọmọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì gbé orí Íṣíbóṣétì tọ Dáfídì wá ní Hébírónì, wọ́n sì wí fún ọba pé, “Wò ó, orí Íṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù ọ̀ta rẹ, tí ó ti ń wá ẹ̀mí rẹ kíri, OLÚWA ti gbẹ̀san fún ọba OLÚWA mi lónìí lára Ṣọ́ọ̀lù àti lára irú-ọmọ rẹ̀.”