2 Samuel 4:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Dafidi dá wọn lóhùn pé, “OLUWA tí ó ti ń yọ mí ninu gbogbo ewu, ni mo fi búra pé,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si da Rekabu ati Baana arakunrin rẹ̀, awọn ọmọ Rimmoni ara Beeroti lohùn, o si wi fun wọn pe, Bi Oluwa ti mbẹ, ẹniti o gbà ẹmi mi lọwọ gbogbo ipọnju,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì dá Rákábù àti Báánà arakùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Rímímónì ará Béérótì lóhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Bí OLÚWA ti ń bẹ, ẹni tí ó gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ gbogbo ìpọ́njú.