2 Samuel 5:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Hiramu ọba Tire rán àwọn oníṣẹ́ sí Dafidi. Ó fi igi Kedari ranṣẹ sí i, pẹlu àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, ati àwọn tí wọn ń fi òkúta kọ́ ilé, pé kí wọ́n lọ kọ́ ààfin Dafidi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hiramu ọba Tire si rán awọn iranṣẹ si Dafidi, ati igi kedari, ati awọn gbẹnàgbẹnà, ati awọn ti ngbẹ́ okuta ogiri: nwọn si kọ́ ile kan fun Dafidi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Hírámù ọba Tírè sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Dáfídì, àti igi kédárì, àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn tí ń gbẹ́ òkúta, wọ́n kọ́ ilé kan fún Dáfídì.