2 Samuel 5:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ pé wọ́n ti fi Dafidi jọba Israẹli, gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jáde lọ láti mú un, ṣugbọn Dafidi gbọ́ pé wọ́n ń bọ̀ wá mú òun, ó bá lọ sí ibi ààbò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nigbati awọn Filistini gbọ́ pe, nwọn ti fi Dafidi jọba lori Israeli, gbogbo awọn Filistini si goke wá lati wa Dafidi; Dafidi si gbọ́, o si sọkalẹ lọ si ilu odi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Fílístínì gbọ́ pé, wọ́n ti fi Dáfídì jọba lórí Ísírẹ́lì, gbogbo àwọn Fílístínì sì gòkè wá láti wá Dáfídì; Dáfídì sì gbọ́, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú olódì.