2 Samuel 5:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi bi OLUWA pé, “Ṣé kí n kọlu àwọn ará Filistia, ṣé o óo fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn?” OLUWA dá a lóhùn pé, “Kọlù wọ́n, n óo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si bere lọdọ Oluwa, pe, Ki emi ki o goke tọ̀ awọn Filistini bi? iwọ o fi wọn le mi lọwọ bi? Oluwa si wi fun Dafidi pe, Goke lọ: nitoripe, dajudaju emi o fi awọn Filistini le ọ lọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì béèrè lọ́dọ̀ OLÚWA pé, “Kí èmi ó gòkè tọ àwọn Fílístínì bí? Ìwọ ó fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ bí?” OLÚWA sì wí fún Dáfídì pé, “Gòkè lọ, nítorí pé dájúdájú èmi ó fi àwọn Fílístínì lé ọ lọ́wọ́.”