2 Samuel 5:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Látẹ̀yìn wá, nígbà tí Saulu pàápàá wà lórí oyè, ìwọ ni o máa ń kó àwọn ọmọ Israẹli lọ sógun. OLUWA sì ti ṣèlérí fún ọ pé, ìwọ ni o óo jẹ́ aṣiwaju àwọn eniyan rẹ̀, ati ọba wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati nigba atijọ, nigbati Saulu fi jọba lori wa, iwọ ni ẹniti ima ko Israeli jade, iwọ ni si ma mu wọn bọ̀ wá ile: Oluwa si wi fun ọ pe, Iwọ o bọ́ Israeli awọn enia mi, iwọ o si jẹ olori fun Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti nígbà àtijọ́, nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù fi jọba lórí wa, ìwọ ni ẹni tí ó máa ń kó Ísírẹ́lì jáde, ìwọ sì ni ó máa ń mú wọn bọ̀ wá ilé: OLÚWA sì wí fún ọ pé, ‘Ìwọ ó ṣe olùsọ́ Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn mi, ìwọ ó sì jẹ́ olórí fún Ísírẹ́lì.’ ”