2 Samuel 5:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi bá wá sí Baali Perasimu, ó sì ṣẹgun àwọn ará Filistia níbẹ̀. Ó ní, “Bí ìkún omi tí í ya bèbè rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA fọ́n àwọn ọ̀tá mi ká níwájú mi.” Ó bá pe orúkọ ibẹ̀ ní Baali Perasimu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si de Baal-perasimu, Dafidi si pa wọn nibẹ, o si wipe, Oluwa ti ya lù awọn ọtá mi niwaju mi, gẹgẹ bi omi iti ya. Nitorina li on ṣe pe orukọ ibẹ na ni Baal-perasimu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì dé Baal-Perasímù, Dáfídì sì pa wọ́n níbẹ̀, ó sì wí pé, “OLÚWA ti ya lu àwọn ọta mi níwájú mi, gẹ́gẹ́ bí omi ti ń ya.” Nítorí náà ni òun ṣe pe orúkọ ibẹ̀ náà ni Baal-Perasímù.