2 Samuel 5:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí o bá gbọ́ ìró kan, tí ó bá dàbí ẹni pé, eniyan ń fi ẹsẹ̀ kilẹ̀ lọ lórí àwọn igi, ni kí o tó kọlù wọ́n, nítorí pé, OLUWA ti kọjá lọ níwájú rẹ láti ṣẹgun àwọn ọmọ ogun Filistini.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yìo si ṣe, nigbati iwọ ba gbọ́ iro ẹsẹ lori awọn igi Baka na, nigbana ni iwọ o si yara, nitoripe nigbana li Oluwa yio jade lọ niwaju rẹ, lati kọlu ogun awọn Filistini.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yóò sì ṣe, nígbà tí ìwọ bá gbọ́ ìró ẹṣẹ̀ lórí àwọn igi Bákà náà, nígbà náà ni ìwọ yóò sì yára, nítorí pé nígbà náà ni OLÚWA yóò jáde lọ níwájú rẹ láti kọlù ogun àwọn Fílístínì.”