2 Samuel 5:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó yá, Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti ìlú Jerusalẹmu. Àwọn ará Jebusi tí wọn ń gbé ibẹ̀ nígbà náà wí fún Dafidi pé, “O kò lè wọ inú ìlú yìí wá, àwọn afọ́jú ati àwọn arọ lásán ti tó láti lé ọ dànù.” Wọ́n lérò pé Dafidi kò le ṣẹgun ìlú náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ọba ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si lọ Jerusalemu sọdọ awọn ara Jebusi, awọn enia ilẹ na: awọn ti o si ti wi fun Dafidi pe, Bikoṣepe iwọ ba mu awọn afọju ati awọn arọ kuro, iwọ ki yio wọ ìhin wá: nwọn si wipe, Dafidi ki yio lè wá sihin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti ọba àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ sí Jérúsálẹ́mù sọ́dọ̀ àwọn ará Jébúsì, àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà; àwọn tí ó sì ti wí fún Dáfídì pé, “Bí kò ṣe pé ìwọ bá mú àwọn afọ́jú àti àwọn arọ́ kúrò, ìwọ kì yóò wọ ìhín wá” wọ́n sì wí pé, “Dáfídì kì yóò lè wá síhìn ín.”