2 Samuel 5:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn tí Dafidi ti ṣẹgun ìlú olódi náà, ó ń gbé inú rẹ̀, ó sì yí orúkọ ibẹ̀ pada sí “Ìlú Dafidi”. Ó kọ́ ìlú náà yíká, bẹ̀rẹ̀ láti Milo, níbi tí wọ́n ti kún ilẹ̀ ní ìhà ìwọ̀ oòrùn òkè náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si joko ni ile awọn ọmọ-ogun ti o ni odi, a si npè e ni ilu Dafidi. Dafidi mọ ògiri yi i ka lati Millo wá, o si kọ ile ninu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì jókòó ní ilé àwọn ọmọ ogun tí ó ní odi, a sì ń pè é ní ìlú Dáfídì. Dáfídì mọ ìgànná yí i ká láti Mílò wá, ó sì kọ́ ilé nínú rẹ̀.