2 Samuel 6:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí wọ́n ti gbé àpótí ẹ̀rí náà wọ inú ìlú Dafidi, Mikali ọmọ Saulu yọjú wo òde láti ojú fèrèsé, ó rí Dafidi ọba tí ó ń jó tí ó sì ń fò sókè níwájú OLUWA, Mikali sì kẹ́gàn rẹ̀ ninu ọkàn rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi apoti-ẹri Oluwa si ti wọ̀ ilu Dafidi wá; Mikali ọmọbinrin Saulu si wò lati oju ferese, o si ri Dafidi ọba nfò soke o si njo niwaju Oluwa; on si kẹgàn rẹ̀ li ọkàn rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí àpótí-ẹ̀rí OLÚWA sì ti wọ ìlú Dáfídì wá; Mikali ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù sì wo láti ojú fèrèsé, ó sì rí Dáfídì ọba ń fò sòkè ó sì ń jó níwájú OLÚWA; òun sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀.