2 Samuel 6:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó sì pín oúnjẹ fún gbogbo wọn, lọkunrin ati lobinrin. Ó fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ìṣù àkàrà kọ̀ọ̀kan, ati ègé ẹran kọ̀ọ̀kan, ati àkàrà tí wọ́n fi èso resini sí ninu. Lẹ́yìn náà, olukuluku lọ sí ilé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si pin fun gbogbo awọn enia na, ani fun gbogbo ọpọ enia Israeli, ati ọkunrin ati obinrin; fun olukuluku iṣu akara kan ati ẹkirí ẹran kan, ati akara didun kan. Gbogbo awọn enia na si tuka lọ, olukuluku si ile rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì pín fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, àní fún gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn Ísírẹ́lì, àti ọkùnrin àti obìnrin; fún olúkúlùkù ìṣù àkàrà kan àti èkìrí ẹran kan, àti àkàrà díndín kan. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì túká lọ, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀.