2 Samuel 6:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó kó wọn lọ sí Baala ní Juda láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọrun wá sí Jerusalẹmu. Orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni wọ́n fi ń pe àpótí ẹ̀rí náà, ìtẹ́ rẹ̀ sì wà lórí àwọn Kerubu tí ó wà lókè àpótí náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si dide, o si lọ, ati gbogbo awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀, lati Baale ti Juda wá, lati mu apoti-ẹri Ọlọrun ti ibẹ wá, eyi ti a npè orukọ rẹ̀ ni orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun ti o joko lãrin awọn Kerubu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì dìde, ó sì lọ àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ́ lọ́dọ̀ rẹ́, láti Báálà Júdà wá, láti mú àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run tí ibẹ̀ wá, èyí tí a ń pe orúkọ rẹ̀ ní orúkọ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun tí ó jókòó láàrin àwọn kérúbù.