2 Samuel 6:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n parí, Dafidi pada sí ilé láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀. Mikali, ọmọ Saulu, bá lọ pàdé rẹ̀, ó ní, “Ọba Israẹli mà dárà lónìí! Ọba yán gbogbo aṣọ kúrò lára, bí aláìlóye eniyan níwájú àwọn iranṣẹbinrin àwọn iranṣẹ rẹ̀!”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si yipada lati sure fun awọn ara ile rẹ̀, Mikali ọmọbinrin Saulu si jade lati wá pade Dafidi, o si wipe, Bi o ti ṣe ohun ogo to loni fun ọba Israeli, ti o bọ ara rẹ̀ silẹ loni loju awọn iranṣẹbinrin awọn iranṣẹ rẹ̀, gẹgẹ bi ọkan ninu awọn enia asan iti bọra rẹ̀ silẹ!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì yípadà láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀, Míkálì ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù sì jáde láti wá pàdé Dáfídì, ó sì wí pé, “Báwo ni ọba Ísírẹ́lì ṣe ṣe ara rẹ̀ lógo bẹ́ẹ̀ lónìí, tí ó bọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ lónìí lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn lásán tí ń bọ́ra rẹ̀ sílẹ̀.”