2 Samuel 6:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi dá a lóhùn pé, “Ijó ni mò ń jó, níwájú OLUWA tí ó yàn mí dípò baba rẹ ati gbogbo ìdílé rẹ̀, láti fi mí ṣe alákòóso Israẹli, àwọn eniyan OLUWA. N óo tún máa jó níwájú OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si wi fun Mikali pe, Niwaju Oluwa ni, ẹniti o yàn mi fẹ jù baba rẹ lọ, ati ju gbogbo idile rẹ̀ lọ, lati fi emi ṣe olori awọn enia Oluwa, ani lori Israeli, emi o si ṣire niwaju Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì wí fún Míkálì pé, “Níwájú OLÚWA ni, ẹni tí ó yàn mí fẹ́ ju baba rẹ lọ, àti ju gbogbo ìdílé rẹ lọ, láti fi èmi ṣe olórí àwọn ènìyàn OLÚWA, àní lórí Ísírẹ́lì, èmi ó sì ṣúre níwájú OLÚWA.