2 Samuel 6:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí jáde kúrò ní ilé Abinadabu tí ó wà lórí òkè, wọ́n sì gbé e ka orí kẹ̀kẹ́ tuntun kan. Usa ati Ahio ọmọ Abinadabu sì ń ti kẹ̀kẹ́ náà;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si gbe apoti-ẹri Ọlọrun na gun kẹkẹ́ titun kan, nwọn si mu u lati ile Abinadabu wá, eyi ti o wà ni Gibea: Ussa ati Ahio, awọn ọmọ Abinadabu si ndà kẹkẹ́ titun na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run náà gun kẹ̀kẹ́ tuntun kan, wọ́n sì mú un láti ilé Ábínádábù wá, èyí tí ó wà ní Gíbéà: Úsà àti Áhíò, àwọn ọmọ Ábínádábù sì ń dá kẹ̀kẹ́ tuntun náà.