2 Samuel 6:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí jó níwájú OLUWA, wọ́n sì ń kọrin pẹlu gbogbo agbára wọn. Wọ́n ń lu àwọn ohun èlò orin olókùn tí wọ́n ń pè ní hapu, ati lire; ati ìlù, ati ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ati aro.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi ati gbogbo ile Israeli si ṣire niwaju Oluwa lara gbogbo oniruru elò orin ti a fi igi arere ṣe, ati lara duru, ati lara psalteri, ati lara timbreli, ati lara korneti, ati lara aro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì sì ṣiré níwájú OLÚWA lára gbogbo onírúurúu èlò orin àti ìlù háàpù, ní ara tanborí, sisitirumù àti kíńbálì.