2 Samuel 6:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Inú bí Dafidi gidigidi nítorí pé OLUWA lu Usa pa. Láti ìgbà náà ni wọ́n ti ń pe ibẹ̀ ní Peresi Usa, títí di òní olónìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Inu Dafidi si bajẹ nitoriti Oluwa ke Ussa kuro: o si pe orukọ ibẹ na ni Peresi-Ussa titi o fi di oni yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Inú Dáfídì sì bàjẹ́ nítorí tí OLÚWA gé Úsà kúrò: ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Peresí-Úsà títí ó fi di òní yìí.