2 Samuel 7:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo yan ibìkan fún Israẹli, àwọn eniyan mi, n óo sì fìdí wọn múlẹ̀ níbẹ̀. Wọn yóo máa gbé ilẹ̀ wọn, ẹnikẹ́ni kò sì ní ni wọ́n lára, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹni ibi kò ní yọ wọ́n lẹ́nu mọ́
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si yàn ibi kan fun awọn enia mi, ani Israeli, emi o si gbìn wọn, nwọn o si ma joko ni ibujoko ti wọn, nwọn kì yio si ṣipo pada mọ; awọn ọmọ enia buburu kì yio si pọn wọn loju mọ, bi igba atijọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi ó sì yan ibìkan fún àwọn ènìyàn mi, àní Ísírẹ́lì, èmi ó sì gbìn wọ́n, wọn ó sì má gbé bí ibùjókòó ti wọn, wọn kì yóò sì ṣípò padà mọ́; àwọn ọmọ ènìyàn búburú kì yóò sì pọ́n wọn lójú mọ́, bí ìgbà àtijọ́.