2 Samuel 7:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Orúkọ rẹ yóo sì lókìkí títí lae, gbogbo eniyan ni yóo sì máa wí títí lae pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni Ọlọrun Israẹli. O óo sì mú kí arọmọdọmọ mi wà níwájú rẹ títí laelae.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jẹ ki orukọ rẹ ki o ga titi lai, pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li Ọlọrun lori Israeli: si jẹ ki a fi idile Dafidi iranṣẹ rẹ mulẹ niwaju rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jẹ́ kí orúkọ rẹ ó ga títí láé, pé, ‘OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni Ọlọ́run lórí Ísírẹ́lì!’ Sì jẹ́ kí a fi ìdílé Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ.