2 Samuel 7:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ninu gbogbo bí mo ti ṣe ń bá àwọn ọmọ Israẹli kiri, ǹjẹ́ mo bèèrè lọ́wọ́ ọ̀kan ninu àwọn olórí wọn tí mo yàn láti jẹ́ alákòóso àwọn eniyan mi, pé, Kí ló dé tí wọn kò fi igi kedari kọ́ ilé fún mi?’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni ibi gbogbo ti emi ti nrin larin gbogbo awọn ọmọ Israeli, emi ko ti iba ọkan ninu ẹya Israeli, ti emi pa aṣẹ fun lati ma bọ awọn enia mi ani Israeli sọ̀rọ pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi kedari kọ ile fun mi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ibi gbogbo tí èmi ti ń rìn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ǹjẹ́ èmi ti bá ọ̀kan nínú ẹ̀yà Ísírẹ́lì, tí èmi pa àṣẹ fún láti máa bọ́ àwọn ènìyàn mi àní Ísírẹ́lì, sọ̀rọ̀ pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi kédárì kọ́ ilé fún mi.” ’