2 Samuel 7:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nítorí náà, sọ fún Dafidi iranṣẹ mi pé, ‘Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo mú un kúrò níbi tí ó ti ń ṣọ́ àwọn aguntan, ninu pápá, mo sì fi jọba Israẹli, àwọn eniyan mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ, nitorina, bayi ni iwọ o si wi fun iranṣẹ mi ani Dafidi pe, Bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, emi ti mu iwọ kuro lati inu agbo agutan wá, lati má mã tẹle awọn agutan, mo si fi ọ jẹ olori awọn enia mi, ani Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ǹjẹ́, nítorí náà, báyìí ni ìwọ yóò sì wí fún ìránṣẹ́ mi àní Dáfídì pé, ‘Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi ti mú ìwọ kúrò láti inú agbo àgùntàn wá láti má tẹ̀lé àwọn àgùntàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórí àwọn ènìyàn mi, àní Ísírẹ́lì.