2 Samuel 8:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi ọba ya àwọn ẹ̀bùn náà sí mímọ́ fún ìlò ninu ilé OLUWA, pẹlu gbogbo fadaka ati wúrà tí ó rí kó láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó ti ṣẹgun;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi ọba si fi wọn fun Oluwa, pẹlu fadaka, ati wura ti o ti yà si mimọ́, eyi ti o ti gbà lọwọ awọn orilẹ-ède ti o ti ṣẹgun;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì ọba sì fi wọ́n fún OLÚWA pẹ̀lú fàdákà, àti wúrà tí ó yà sí mímọ́, èyí tí ó ti gbà lọ́wọ́ àwọn orilẹ̀-èdè tí ó ti ṣẹ́gun.