2 Samuel 8:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi bá kọ́ àgọ́ àwọn ọmọ ogun kan sí Aramu, ní Damasku, gbogbo àwọn ará Siria sì ń sin Dafidi, wọ́n sì ń san owó ìṣákọ́lẹ̀ fún un. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si fi awọn ologun si Siria ti Damasku: awọn ara Siria si wa sìn Dafidi, nwọn a si ma mu ẹbùn wá. Oluwa si pa Dafidi mọ nibikibi ti o nlọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì fi àwọn ológún sí Síríà ti Dámásíkù: àwọn ará Síríà sì wá sin Dáfídì, wọn a sì máa mú ẹ̀bùn wá, OLÚWA sì pa Dáfídì mọ́ níbikíbi tí o ń lọ.