2 Samuel 9:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìwọ, àwọn ọmọ rẹ, ati àwọn iranṣẹ rẹ, ni ẹ óo máa ro gbogbo oko Saulu; ẹ ó máa kórè àwọn ohun ọ̀gbìn tí ẹ bá gbìn, kí ọmọ oluwa yín lè ní oúnjẹ tó, ṣugbọn Mẹfiboṣẹti alára, yóo máa wá jẹun lórí tabili mi nígbà gbogbo.” Àwọn ọmọkunrin tí Siba ní nígbà náà jẹ́ mẹẹdogun, àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì jẹ́ ogún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn iranṣẹ rẹ ni yio si ma ro ilẹ na fun u, iwọ ni yio si ma mu ikore wá, ọmọ oluwa rẹ yio si ma ri onjẹ jẹ: ṣugbọn Mefiboṣeti ọmọ oluwa rẹ̀ yio si ma ba mi jẹun nigbagbogbo ni ibi onjẹ mi. Siba si ni ọmọ mẹ̃dogun ati ogún iranṣẹkunrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ, àti àwọn ọmọ rẹ, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ ni yóò sì máa ró ilé náà fún un, ìwọ ni yóò sì máa mú ìkóre wá, ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa rí òunjẹ jẹ: ṣùgbọ́n Méfibóṣétì ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.” (Ṣíbà sì ní ọmọ mẹ́ẹ̀dógún àti ogún ìránṣẹ́kùnrin.)