2 Samuel 9:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Siba dáhùn pé, gbogbo ohun tí ọba pa láṣẹ ni òun yóo ṣe. Mẹfiboṣẹti bá bẹ̀rẹ̀ sí jẹun lórí tabili ọba, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Siba si wi fun ọba pe, Gẹgẹ bi gbogbo eyi ti oluwa mi ọba ti pa li aṣẹ fun iranṣẹ rẹ, bẹ̃na ni iranṣẹ rẹ o si ṣe. Ọba si wi pe, Niti Mefiboṣeti, yio ma jẹun ni ibi onjẹ mi, gẹgẹ bi ọkan ninu awọn ọmọ ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣíbà sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí OLÚWA mi ọba ti pa láṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni ìránṣẹ́ rẹ ó ṣe.” Ọba sì wí pé, “Ní ti Méfibóṣétì, yóò máa jẹun ní ibi oúnjẹ mi, Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọba.”