2 Samuel 9:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọkunrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Siba, tí ó ti jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ Saulu nígbà ayé rẹ̀. Wọ́n pè é wá fún Dafidi, Dafidi sì bi í pé, “Ṣé ìwọ ni Siba?” Siba dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, oluwa mi, èmi ni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iranṣẹ kan si ti wà ni idile Saulu, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Siba. Nwọn si pè e wá sọdọ Dafidi, ọba si bere lọwọ rẹ̀ pe, Iwọ ni Siba bi? O si dahùn wipe, Iranṣẹ rẹ ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìránṣẹ́ kan sì ti wà ní ìdílé Ṣọ́ọ̀lù, orúkọ rẹ̀ sí ń jẹ́ Síbà, Wọ́n sì pèé wá sọ́dọ̀ Dáfídì, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ìwọ ni Síbà bí?” Ó sì dáhùn wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni.”