2 Samuel 9:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba tún bi í pé, “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni kù ninu ìdílé Saulu, tí mo lè fi àánú Ọlọrun hàn, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣèlérí fún Ọlọrun pé n óo ṣe?” Siba dá a lóhùn pé, “Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Jonatani wà láàyè, ṣugbọn arọ ni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si wipe, Kò ha si ọkan ninu idile Saulu sibẹ, ki emi ki o ṣe ore Ọlọrun fun u? Siba si wi fun ọba pe, Jonatani ní ọmọ kan sibẹ ti o ya arọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì wí pé, “Kò ha sí ọ̀kan nínú ìdílé Ṣọ́ọ̀lù ṣíbẹ̀, kí èmi ṣe ooré Ọlọ́run fún un?” Ṣíbà sì wí fún ọba pé, “Jónátanì ní ọmọ kan ṣíbẹ̀ tó ya arọ.”