2 Samuel 9:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, oore ni mo fẹ́ ṣe ọ́ nítorí Jonatani baba rẹ. Gbogbo ilẹ̀ tí ó ti jẹ́ ti Saulu baba baba rẹ rí, ni n óo dá pada fún ọ, a óo sì jọ máa jẹun lórí tabili mi nígbà gbogbo.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si wi fun u pe, Máṣe bẹ̀ru: nitoripe nitotọ emi o ṣe ore fun ọ nitori Jonatani baba rẹ, emi o si tun fi gbogbo ilẹ Saulu baba rẹ fun ọ: iwọ o si ma ba mi jẹun nigbagbogbo ni ibi onjẹ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù: nítorí pé nítòótọ́ èmi ó ṣe oore fún ọ nítorí Jónátanì baba rẹ, èmi ó sì tún fi gbogbo ilé Ṣọ́ọ̀lù baba rẹ fún ọ: ìwọ ó sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.”