2 Thessalonians 1:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
nígbà tí Oluwa bá dé ní ọjọ́ náà láti gba ògo lọ́dọ̀ àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀, nígbà tí gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ yóo máa yẹ́ ẹ sí, nítorí wọ́n gba ẹ̀rí tí a jẹ́ fún wọn gbọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o ba de lati jẹ ẹni ãyìn logo ninu awọn enia mimọ́ rẹ̀, ati ẹni iyanu ninu gbogbo awọn ti o gbagbọ́ (nitori a ti gbà ẹrí ti a jẹ fun nyin gbọ) li ọjọ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ tí yóò jẹ́ ẹni tí a ó yìn lógo nínú àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àti ẹni àwòyanu ní àárin gbogbo àwọn tí ó ti gbàgbọ́. Èyí kò yọ yín sílẹ̀, nítorí ẹ ti gba ẹ̀rí tí a jẹ́ sí yín gbọ́.