2 Thessalonians 2:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ó yẹ kí á máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nítorí yín, ẹ̀yin ará, àyànfẹ́ Oluwa, nítorí Ọlọrun ti yàn yín láti ìbẹ̀rẹ̀ wá láti gbà yín là nípa Ẹ̀mí tí ó sọ yín di mímọ́, ati nípa gbígba òtítọ́ gbọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn iṣẹ wa ni lati mã dupẹ lọwọ Ọlọrun nigbagbogbo nitori nyin, ará, olufẹ nipa ti Oluwa, nitori lati àtetekọṣe li Ọlọrun ti yàn nyin si igbala ninu isọdimimọ́ Ẹmí ati igbagbọ́ otitọ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n, ohun tí ó tọ́ fún wa ni láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ará olùfẹ́ ní ti Olúwa, nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn yín sí ìgbàlà nípa ìṣọdi-mímọ́ ti Ẹ̀mí àti nípa gbígba òtítọ́ gbọ́.