2 Thessalonians 2:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ dúró ṣinṣin, kí ẹ di àwọn ẹ̀kọ́ tí a fi le yín lọ́wọ́ mú, kì báà ṣe àwọn tí a kọ yín nípa ọ̀rọ̀ ẹnu tabi nípa ìwé tí à ń kọ si yín. Bẹ́ẹ̀ ni àwa náà gbà á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, ará, ẹ duro ṣinṣin, ki ẹ si dì ẹkọ́ wọnni mu ti a ti fi kọ́ nyin, yala nipa ọ̀rọ, tabi nipa iwe wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà ará, ẹ dúró sinsin, kí ẹ sì di àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀n-ọn-nì tí a kọ́ yín mú, yálà nípa ọ̀rọ̀ ẹnu tàbí lẹ́tà.