2 Timothy 1:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
tí ó gbà wá là, tí ó pè wá láti ya ìgbé-ayé wa sọ́tọ̀. Kì í ṣe pé ìwà wa ni ó dára tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi pè wá. Ṣugbọn ó pè wá gẹ́gẹ́ bí ètò tí òun fúnrarẹ̀ ti ṣe, ati nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí ó fi fún wa nípasẹ̀ Kristi Jesu láti ayérayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti o gbà wa là, ti o si fi ìpe mimọ́ pè wa, kì iṣe gẹgẹ bi iṣe wa, ṣugbọn gẹgẹ bi ipinnu ati ore-ọfẹ tirẹ̀, ti a fifun wa ninu Kristi Jesu lati aiyeraiye,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ẹni ti ó gbà wá là, ti ó si pè wá sínú ìwà-mímọ́—kì í ṣe nípa iṣẹ́ tí a ṣe ṣùgbọ́n nípaṣẹ̀ ète àti oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. Oore-ọ̀fẹ́ yìí ni a fi fún wa láti ìpìlẹ̀ ayérayé,