2 Timothy 2:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, mo farada ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́, kí àwọn náà lè rí ìgbàlà tí ó wà ninu Kristi Jesu pẹlu ògo tí ó wà títí lae.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina mo nfarada ohun gbogbo nitori ti awọn ayanfẹ, ki awọn na pẹlu le ni igbala ti mbẹ ninu Kristi Jesu pẹlu ogo ainipẹkun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà mo ń faradà ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́; kí àwọn náà pẹ̀lú lè ní ìgbàlà tí ń bẹ nínú Kírísítì Jésù pẹ̀lú ògo ayérayé.