2 Timothy 2:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Máa rán àwọn eniyan létí nípa nǹkan wọnyi. Kìlọ̀ fún wọn níwájú Ọlọrun pé kí wọn má máa jiyàn lórí oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ tí kò wúlò, tíí sìí máa da àwọn tí ó bá gbọ́ lọ́kàn rú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nkan wọnyi ni ki o mã rán wọn leti, mã kìlọ fun wọn niwaju Oluwa pe, ki nwọn ki o máṣe jijà ọ̀rọ ti kò lere, fun iparun awọn ti ngbọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nǹkan wọ̀nyí ni ki ó máa rán wọn létí. Máa kìlọ̀ò fún wọn níwajú Olúwa pé, ki wọn ó yẹra kúrò nínú jíjiyàn ọ̀rọ̀ tí kò léèrè, bí kò ṣe ìparun fún àwọn tí ń gbọ́.