2 Timothy 2:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Ọlọrun ti fi ìpìlẹ̀ yìí lélẹ̀, tí ó dúró gbọningbọnin. Àkọlé tí a kọ sára èdìdì tí ó wà lára rẹ̀ nìyí: “Ọlọrun mọ àwọn ẹni tirẹ̀,” ati pé, “Gbogbo àwọn tí ó bá ń pe orúkọ Oluwa níláti kúrò ninu ibi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ipilẹ Ọlọrun ti o daju duro ṣinṣin, o ni èdidi yi wipe, Oluwa mọ̀ awọn ti iṣe tirẹ̀. Ati pẹlu, ki olukuluku ẹniti npè orukọ Oluwa ki o kuro ninu aiṣododo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ìpìlẹ̀ Ọlọ́run tí ó dájú dúró ṣinṣin, ó ní èdìdì yìí, pé, “Olúwa mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀.” Àti pẹ̀lú, “Kí olúkúlùkù ẹni tí ń pé orúkọ Olúwa kúró nínú àìṣòdodo.”